PROTECTION

PROTECTION

Life is full of risks and unexpected occurences and attacks from all fronts. Unless one is well protected, one is prone to become a victim and sometimes to the extent of losing one’s life, spouse’s life, children’s life or become physically or mentally incapacitated. There is the need for one to constantly check his/her well being and provide adequate protection not only for oneself but also for other members of one’s family against these vagaries of life and evil machinations of the enemy, African Heritage Naturalist Care Ltd is equal to the task of providing efficacious preparation to ward off evil and give maximum protection by the good grace of God. In a stanza of {Òtúrúpọ̀n-Òfùn}, ifá says.

Arúgbó ilé wa tó seyín gọngọ sími
Bẹ́ẹ̀ni ò gbọdọ̀ fi gun mi
Bẹ́ẹ̀ni ò gbọdọ̀ fi bu ọmọ mi jẹ
Ọ̀mìmì kan ò gbọdọ̀ milẹ̀
Dífá fun Ọbalùfọ̀n òlélé
Èyí to nrayé akọ́mọ́jọ
Ifá ràtà bòmí
Kó o tún ràtà bo ọmọ mi
Bí afẹ́fẹ́ bá fẹ́
Ìhùhù l’adìẹ fi ńbo ọmọ ẹ̀ mọ́lẹ̀

Translation:
The aged in our house that protrudes her teeth towards me
She dare not use it on me
Neither does she use it to bite my children
Nothing must ever happen
This was the ifá cast for Ọbalùfọ̀n òlélé
When going to the world where they gather children
Ifá please spread your protective shield over me
Also extend it to my children
When the wind blows
Hen uses its plumes to protect its children.

In a stanza of Ìrosùn Ìwòrì, Ifá says:

Olóko lójí ló rú iná túú
Bẹ́ẹ̀ni ò pa alágẹmọ jẹ
Díá fún Ọ̀rúnmìlà
Baba yóó ràtà bo ọmọ rẹ̀ nítorí ikú
Ọ̀rúnmìlà ràtà bò mí ikú pọ̀ lóde
Ojú oró níí ràtà bo omi
Ọ̀rúnmìlà ràtà bò mí ikú pọ̀ lóde
Òsíbàtà níí ràtà bo odò
Ọ̀rúnmìlà ràtà bò mí ikú pọ̀ lóde
Omi ńlá níí ràtà bo iyanrì mọ́lẹ̀
Ọ̀rúnmìlà ràtà bò mí ikú pọ̀ lóde
Àtà níí ràtà bo òrùlé
Ọ̀rúnmìlà ràtà bò mí ikú pọ̀ lóde
Fìlà níí ràtà bo orí
Ọ̀rúnmìlà ràtà bò mí ikú pọ̀ lóde

Translation:
The farmer is it makes fire
But dare not roast a chameleon
This was the Ifá cast for Ọ̀rúnmìlà
When he would spread his armour of protection over his children
Ọ̀rúnmìlà please spread your armour of protection me
Ojú oró… Is it that protects the water
Ọ̀rúnmìlà please spread your armour of protection me
Òsíbàtà… Is it that protects the river
Ọ̀rúnmìlà please spread your armour of protection me
The mighty water is it that protects sand underneath the river
Ọ̀rúnmìlà please spread your armour of protection me
Àtà… is it that protects the roof
Ọ̀rúnmìlà please spread your armour of protection me
The cap… Is it that protects the head Ọ̀rúnmìlà please spread your armour of protection me